Wo dúkìá 45 tó jẹ́ ti agbẹjọ́rò àgbà l'bẹ́ ìjọba Buhari, Abubakar Malami tí ilé ẹjọ́ gbẹ́sẹ̀lé

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ile ẹjọ giga kan nillu Abua ti paṣẹ ki ijọba gbẹsẹ le dukia ti iye rẹ le ni ogoji to jẹ ti adajọ agba Naijiria tẹlẹ, Abubakar Malami.
Adajọ Joyce Abdulmalik gba ẹbẹ EFCC wọle pe ki wọn gbẹsẹ le awọn dukia naa lẹyin ti agbejọro Malami kuna lati ṣalaye pe ki n ṣe nipa ọna eburu lo fi ni awọn dukia naa.
Ṣaaju idajọ rẹ ni adajọ ọhun kọ oniruru ẹbẹ Malami lẹyin to ni wọn ko lẹsẹ nilẹ.
O ni ọrọ to wa niwaju oun kii ṣe "ta lo ni dukia" bi ko ṣe pe bawo ni wọn ṣe ko dukia naa jọ.
Gẹgẹ bi adajọ ọhun ṣe sọ, afurasi naa ko sọ pe kii ṣe ọna eburu loun fi ko ọrọ ọhun jọ.
Abala kẹtadinlogun ofin iwa jibiti, iyẹn Advance Fee Fraud and Other Fraud Related Offences Act lo fi gbe idajọ rẹ kalẹ.
Amọ adajọ ọhun gbẹsẹ kuro lori awọn dukia kan ti wọn ti gbẹsẹle ṣaaju.
Ninu oṣu Kinni ọdun 2026 yii ni EFCC rọ ile ẹjọ pe ko gba oun laaye lati gbẹsẹle dukia mẹtadinlọgọta to jẹ ti afurasi ọhun eyii ti iye owo rẹ to ₦212.8 biliọnu.

Oríṣun àwòrán, EFCC
Lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kinni ti ile ẹjọ n lọ fun isinmi lo ni ki wọn gbẹsẹle awọn dukia naa fun igba diẹ.
O wa paṣẹ fun EFCC lọjọ naa pe ko kede ninu awọn iwe iroyin ki ẹnikẹni to ba ro pe ko yẹ ki wọn gbẹṣẹle awọn dukia naa lati wa ṣalaye eredi niwaju oun.
Ilu Abuja, Kano, Kebbi ati Kaduna lawọn dukia naa wa.

Oríṣun àwòrán, EFCC
Lẹyin ikede EFCC ni Malami funra rẹ, iyawo rẹ Nana Hadiza Malami, ati ọmọ rẹ, Abdulaziz Abubakar atawọn ileeṣẹ mii ti wọn ni nnkan lati ṣe pẹlu awọn dukia naa pe ẹjọ tako igbesẹ ọhun.
Wọn ni ki ile ẹjọ da ẹjọ EFCC nu ko si wọgile aṣẹ to ni ki wọn gbẹsẹle awọn dukia naa nitori ko ba ofin mu lati ṣe bẹẹ.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ọna to tọ ati eyii to ba ofin mu ni wọn fi ko dukia naa jọ.

Oríṣun àwòrán, EFCC
Lẹyin ti ile ẹjọ pada de lati isinmi ni wọn gbe ẹjọ ọhun lọ siwaju adajọ Joyce Abdulmalik lati gbọ ati lati gbe idajọ kalẹ lori rẹ.
EFCC ṣalaye pe iwadii oun fi han pe lootọ ni Malami ati gbogbo awọn ti wọn lọwọ ninu awọn dukia naa ko jọ nipa jibiti.
O wa rọ ile ẹjọ ko kuku gbẹsẹle gbogbo dukia ọhun patata.

Oríṣun àwòrán, EFCC
Iwọnyii ni awọn dukia Malami ti ilẹ ẹjo ki wọn gbẹsẹle ati ibi ti wọn wa
- Ile nla kan ni Plot No. 3011, Maitama District, Abuja
- Ile alaja mẹtani No. 3 Onitsha Crescent, Area 11, Garki, Abuja
- Ile alaja maru un ni Plot 683, Jabi District, Abuja (Meethaq Hotels Ltd., Jabi)
- Ile kan ni No. 3130, Asokoro District, Abuja
- Ile kan ni No. 3 Rhine Street, Maitama, Abuja (Meethaq Hotels Ltd., Maitama)
- Ilẹ kan Plot No. 1241B (No. 11A Yakubu Gowon Crescent), Asokoro District, Abuja
- Ṣọọbu ni No. C52, Citiscape–Shariff Plaza, Wuse II, Abuja
- Ile ni No. 4 Ahmadu Bello Way, Nasarawa GRA, Kano
- Ile ni Plot 157, Lamido Nasarawa GRA, Kano
- Ile itaja nla ninu ọja Birnin Kebbi
- Ọgọrun un eeka ilẹ ni Birnin Kebbi–Jega Road
- Ọgọrun un eeka ilẹ miran ni Birnin Kebbi–Jega Road
- Ile oni yara mẹrin, Gesse Phase II, Birnin Kebbi
- Awọn ṣọọbu ni. A36 ati B3, Vegas Mall, Wuse II, Abuja
- Ile ni 26 Babbi Drive, BUA Estate, Abuja
- Ile ni 27 EFAB Estate, Gwarimpa, Abuja
- Ile oniyara mẹrin ni No. 10B Doka Crescent, Abakpa GRA, Kaduna
- Ile ni Plot No. 13, IPENT 7 Estate, Karsana District, Abuja
- Ile olowo nla ni No. 12 Yalinga Street, Wuse II, Abuja
- Ṣọọbu nla ni B40 ati B46, ọja Wuse, Abuja
- Ile nla meji ni, Apo Legislative Quarters, Gudu District, Abuja
- Ile oniyara mẹsan an ni Academic Garden City, Birnin Kebbi
- Ile oniyara meji mẹta ni Academic Garden City, Birnin Kebbi
- Ilẹ eekan marun atabọ ni Academic Garden City, Birnin Kebbi
- Ileeṣẹ Rayhaan Agro Allied ni ipinlẹ Kebbi
- Awọn ile ti ileeṣẹ Rayhaan n lo ni ipinlẹ Kebbi
- Awọn ẹrọ igbalode ti ileeṣẹ Rayhaan n lo ni ipinlẹ Kebbi
- Mọṣalaṣi Rayhaan Factory ni ipinlẹ Kebbi
- Ile ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Rayhaan Mill n gbe ni ipinlẹ Kebbi
- Ile Rayhaan Bustan, ipinlẹ Kebbi
- Gbagede Azbir Arena, ipinlẹ Kebbi
- Ile itura Azbir Hotel, ipinlẹ Kebbi
- Ileeṣẹ Azbir Printing Press, ipinlẹ Kebbi
- Ileeṣẹ Azbir Gallery, ipinlẹ Kebbi
- Ileeṣẹ Azbir Gardens, ipinlẹ Kebbi
- Ileeṣẹ Azbir Mosque, ipinlẹ Kebbi
- Ileeṣẹ Azbir Clothing, ipinlẹ Kebbi
- Ileeṣẹ Azbir Pharmacy and Supermarket, ipinlẹ Kebbi
- Ileeṣẹ Al-Afiya Energy tanker garage, Birnin Kebbi
- Ileeṣẹ Rayhaan Security House, Birnin Kebbi
- Ile itaja meji ti wọn ko tii kọ tan ni Birnin Kebbi
- Ileeṣẹ Amasdul Oil and Gas Ltd., Birnin Kebbi
- Ile, itura Zeennoor Hotel, Kabuga Satellite Town, Kano
- Mọṣalaṣi Kabuga ni Satellite Town, Kano
- Ile itura Old Zeennoor Hotel, Kano
- Fasiti Rayhaan University
























