Ǹjẹ́ Trump le san ẹgbẹ̀rún márùn-ún dọ́là fún èèyàn kọ̀ọ̀kan ní Amẹ́ríkà?

Oríṣun àwòrán, EPA
- Author, Alex Boyd
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Aarẹ Ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti sọ pe oun yoo fun awọn agbalagba kọọkan ni ilẹ Amẹrika ni ẹgbẹrun marun-un-marun-un owo dọla, bi oludije lẹgbẹ oṣelu Republican ba bori eto idibo idaji to n bọ ninu oṣu Kọkanla.
Ṣugbọn ohun ti ko tii foju han ni bi sisan owo naa yoo ṣe lọ, ati pe ọpọ eeyan lo n beere ṣe igbesẹ naa ba ofin mu.
Ọrọ to sọ yii mu ki ọpọ awọn alatilẹyin rẹ nibi ipade gbogboogbo ẹgbẹ to waye l'Ọjọru, ọsẹ yii kan saara si Trump ṣugbọn awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lati Democrats sọ pe "ileri ori ahọn" lasan ni, nigba ti awọn kan n sọ pe ko ba ofin mu.
Trump ko tan imọlẹ si i nipa bi wọn yoo ṣe ṣagbatẹru owo naa, bo tilẹ jẹ pẹ igbakeji rẹ, JD Vance sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn ileeṣẹ to n gba owo ori ni yoo san owo naa, ati pe awọn olowo nilẹ Amẹrika ko nii lanfaani si owo naa.
Njẹ̀ ìgbésẹ̀ Trump bá òfin mu?
Labẹ ofin ijọba ilẹ Amẹrika, o jẹ ohun to tako ofin lati san owo pẹlu erongba lati fi tọka si bi awọn eeyan yoo ṣe dibo.
Ṣugbọn ṣa, awọn akọṣẹmọṣẹ ti sọ pe agbekalẹ Trump to sọ jade ni Texas l'Ọjọru, ni a le ri gẹgẹ bii ẹjẹ lati ge owo ori kuru, eyi to ba ofin mu.
Ọmọwe Joan Mahoney, olukọ ẹkọ imọ ofin ni fasiti Southampton, sọ fun BBC pe oun lero wi pe owo naa yoo ba ofin mu, gẹgẹ bi eyi to fi ara jọ ileri ipolongo idibo - ṣugbọn to sọ pe awọn oloṣelu "kii sabaa ṣe iru ileri to to bẹẹ".
"Lọna miran niṣe lo dabi owo riba, ẹ dibo fun Republican, ki ẹ si gba owo, leyi ti a le sọ pe ko ba ofin mu," o sọ bẹẹ.
"Ṣugbọn ni lọna miran, gbogbo eeyan lo maa jẹ anfaani, lai nii ṣe pẹlu nipa bi awọn eeyan ṣe dibo si, fun idi eyi, a ko le sọ pe owo riba ni.
"Mo lero wi pe o ba ofin mu. Niṣe lo dabi iru ileri wi pe 'bi ẹgbẹ oṣelu mi ba bori, a maa din owo ori ku'. Gbogbo ẹgbẹ oṣelu lo n ṣe bẹẹ ni gbogbo igba...eyi si foju han gbangba wi pe o ba ofin mu."
'Sugbọn ṣa, Laurel Rapp, alakoso agba ni Chattam House nilẹ Amẹrika ati Ariwa Amẹrika, sọ fun BBC pe erongba tuntun ti Trump gbe wa yii "yatọ gedengbe" si ileri ti awọn oludije ti maa n gbe wa lasiko eto idibo.

Oríṣun àwòrán, Justin Sullivan/Getty Images
Éèló ni yóò ná wọn, àti pé ṣé Amẹ́ríkà lè san án?
Yatọ si ibeere nipa biba ofin mu, awọn miran tun n beere pe boya eto iṣuna Trump yoo foju han nipa jijẹ ki gbese ilẹ Amẹrika lọ soke, nipasẹ ogun to n ṣẹẹ ni Iran.
Awọn agbalagba to to ẹgbẹrun lọna igba ati aadọrin (270million) miliọnu lo wa nilẹ Amẹrika, leyi to tunmọ si pe ẹgbẹrun marun-un owo dọla yoo na ijọba Amẹrika ni tiriliọnu kan ati diẹ ($1.3t) owo dọla
Trump ko ṣalaye nipa bi wọn yoo ṣe ṣagbatẹru owo naa lasiko to n sọrọ.
Aarẹ Trump ko tun sọ boya yoo gba aṣẹ lọwọ awọn ile igbimọ aṣofin lati buwọ lu owo naa. Iru eyi ko si ṣẹlẹ ri wi pe yoo buwọ lu iru owo bẹẹ nipa agbara aarẹ.
Erica York, akọṣẹmọṣẹ nipa eto iṣuna nileeṣẹ kan to n ri sọrọ owo ori, eyi to wa niluu Washington DC, sọ fun BBC pe yoo jẹ iyalẹnu foun bi ipade gbogboogbo naa ba buwọ lu aba Trump.
"Eyi yoo jẹ ọkan lara awọn ọna to buru jukọ lati lo tiriliọnu kan ati diẹ ($1.3t) owo dọla," o sọ bẹẹ.
Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin Fox sọrọ lẹyin ọrọ Trump, Vance sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe owo ti aarẹ ba gba nipasẹ owo ori ni wọn yoo fi ṣagbatẹru owo naa.
Ṣugbọn ṣa, owo apawọle titi di asiko yii lo kere sii owo ti wọn yoo nilo lati fi san ẹgbẹrun marun-un owo dọla ti Trump fẹẹ fun awọn eeyan.
Aarẹ ilẹ Amẹrika sọ fawọn oloṣelu Republican nibi ipade gbogboogbo naa pe ilẹ Amẹrika ni wọn yoo ti na owo naa, ṣugbọn ko ye ẹnikẹni bi wọn yoo ṣe tọpinpin owo naa.
Gẹgẹ bi ajọ Bipartisan Policy Center ṣe sọ, ilẹ Amẹrika ti mu owo to din diẹ ni idaji tiriliọnu ($475bn), eyi to jẹ biliọnu mẹtalenigba Yuro (£203bn) le ninu apawọle lati ibẹrẹ ọdun 2025.
Sibẹsibẹ, owo to le ni ọgọrun biliọnu owo dọla ($100bn) ni wọn ti da pada lẹyin idajọ ile ẹjọ agba patapayta, lati ge owo apawọle kuru ni ibẹrẹ ọdun naa.
Nigba to n dahun ibeere nipa bi sisan owo naa yoo ṣe rọrun, ile agba ilẹ Amẹrika, White House sọ ninu atẹjade ti wọn fi ranṣẹ si BBC: "Awọn alala ati awọn onisọkusọ ti bẹrẹ sii ṣiye meji nipa Aarẹ Trump."
"Pẹlu atilẹyin awọn ara ilẹ Amẹrika, Aarẹ Trump yoo tẹsiwaju lati maa mu ileri rẹ ṣẹ," Davis Ingie to jẹ agbẹnusọ sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Kevin Dietsch / Getty Images
Kí ló dé ti Trump gbé ànfàànì yìí wá?
Robert Moran to ti figba kan ri jẹ alagbekalẹ ara ọtọ fun Republican sọ pe agbekalẹ Trump tuntun yii jẹ ohun ti awọn eeyan gbọdọ ṣagbeyẹwo rẹ daadaa, paapaa bi eto idibo ṣe ku oṣu meji ère.
"Ileri ara ọtọ ni eyi jẹ, nko si ni aridaju ibi ti wọn yoo ti ri owo naa - ṣugbọn asiko oṣelu ni a wa yii," Robert Moran sọ fun BBC.
Chatham House's Rapp sọ pe Trump n wa ọna lati fa oju awọn eeyan rẹ mọra nigba ti iṣakoso rẹ ṣẹṣẹ fẹẹ pe ọdun meji
"Owo ni o wa fẹẹ lo bayii nigba to mọ pe eto idibo ko nii ṣe daradara fun awọn Rebublican, bẹẹ si ni eto idibo naa ko nii ṣe daadaa fun oun funra rẹ," o sọ bẹẹ.
Njẹ́ ohun tó farajọ èyí ti ṣẹlẹ̀ rí?
Kii ṣe igba akọkọ ree ti Trump yoo maa ṣeleri sisan owo ree - o ti daba nigba ẹgbẹrun meji owo dọla nigba kan ri, eyi to sọ pe owo apawọle ni wọn yoo fi san owo naa. Awọn owo naa ni ko tii wa si imuṣẹ titi di asiko yii.
Aarẹ tẹlẹri, Joe Biden ni wọn fẹsun fifi owo ra ibo kan, nigba to ṣẹlẹ ẹgbẹrun meji owo dọla gẹgẹ bi owo iranwọ fun ajakalẹ arun Covid fun awọn Amẹrika, iyẹn bi awọn oludije meji lẹgbẹ oṣelu Democrat ni Georgia ba yege ninu eto idibo sile igbimọ aṣofin agba ninu oṣu Kinni, ọdun 2021.
Eyi to fi ara jọ biba ofin mu wa si iwaju ẹni to n lewaju eto idibo aarẹ ọdun 2024, nigba ti alatilẹyin Trump, Elon Must ṣẹleri lati gbe owo kalẹ fun oludibo ni ipinlẹ mẹjọ, bi wọn ba buwọ lu iwe ẹsun kan.





























