Wo àwọn gbankọgbì ìlérí tí àwọn olóṣèlú ti ṣe fáráàlú ní Naijiria

- Author, Olumide Owaduge
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ti asiko eto dibo ba ti n sunmọ etile kaakiri agbaye lawọn oloṣelu maa n ṣe oniruru ileri ti wọn ko le mu ṣe.
Lọpọ igba lawọn ileri naa maa n waye lati jẹ ki araalu dibo fun wọn, nigba mii, wọn maa n ṣe awọn ileri bẹẹ lati fi han pe wọn nifẹ araalu lọkan ju awọn alatako wọn lọ.
Apẹrẹ irufẹ ileri bẹẹ ni Aarẹ Amẹrika, Donald Trump to sọ pe oun yoo fun awọn eeyan ilẹ naa ni ẹgbẹrun marun un dollar ti ẹgbẹ oṣelu Demorcrat ba le wọle ibo ninu oṣu Kọkanla ọdun yii.
Bẹrẹ lati sisan dollar kan di naira kan si ipese ounjẹ ọfẹ faraalu, iwọnyi lawọn ileri ti oloṣelu ti ṣe faraalu ni Naijiria ṣaaju eto idibo bo tilẹ jẹ pe pupọ ilerinaa ni wọn kuna lati muṣẹ.
A maa sọ 1$ di 1 naira – Buhari

Oríṣun àwòrán, Zizoko
Lasiko ti Aarẹ ana, Muhammadu Buhari n ṣe ipolongo ibo lọdun 2019, oniruru ileri lo ṣe faraalu amọ ọrọ owo dollar si naira jẹ ọkan pataki ninu rẹ.
Lara ileri to ṣe ni ipese miliọnu mẹta iṣẹ lọdọdun, fifun awọn akẹkọọ lounjẹ ọfẹ lẹẹkan lojojumọ, sisan owo ajẹmọnu loṣoṣu fun awọn to ti jade ẹkọ giga atawọn to n wa iṣẹ, ṣiṣẹgun ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram, pipese 11,000MW ina mọnamọna ati sisọ dollar kan di naira kan.
Lọdun naa lọhun, N216 ni wọn n ṣẹ dolla si naira amọ Buhari ni ijọba oun yo ja owo naa walẹ patapata.
Lẹyinorẹyin, nigba ti Buhari yoo fi ori alefa silẹ, dolla ti wa ni nkan bii 800 naira.
Mo maa yọ owo iranwọ ori epo bẹntiro; mo maa da owo iranwọ ori epo pada – Atiku

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ti le ni ọgbọn ọdun ti Atiku Abubakar ti n du ipo ni Naijiria, o si ti du ipo Aarẹ fun ọpọ igba amọ niṣe lo n lulẹ.
Lara awọn ileri ti Atiku Abubakar ṣe lọdun 2023 ni pe oun yoo fopin si owo iranwọ ori epo bẹntiro fun anfani awọn araalu.
Amọ iyalẹnu lo jẹ nigba ti yoo di ọdun 2026 yii, Atiku yi ẹnu pada pe ti oun ba le wọle sipo Aarẹ lọdun 2027, oun yoo da owo iranwọ ori epo naa pada lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu ti yọ danu.
Atiku ni ọpalamba iya ni igbeṣe ọhun fi n jẹ ọmọ Naijiria lẹyin ọwọngogo to tẹlẹ.
Idanwo WAEC ati NECO yoo di ọfẹ; N500,000 owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ - Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu AAC, Omoyele Sowore ti sọ pe awọn akẹkọọjade nile ẹkọ girama ko ni san owo indanwo mọ ti oun ba di Aarẹ.
O tun sọ pe owo oṣu to kere julọ ti awọn oṣiṣẹ yo maa gba yoo di N500,000 labẹ ijọba oun.
Sowore sọ pe orilẹede ọlọrọ ni Naijiria nitori naa, lati san awọn owo yii ko ni ṣoro rara.
Mo maa ṣe ina Solar si orule gbogbo ọmọ Naijiria – Adebayo Adewole

Oríṣun àwòrán, Instagram/Adewole Adebayo
Lasiko to n ba ileeṣẹ iroyin Arise sọrọ ni Adewole sọrọ yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, kaakri orilẹede Naijiria ni ijọba rẹ yoo da ileeṣẹ to n ṣe solar naa si fun anfani gbogbo ọmọ Naijiria.
O ni "Mo ṣeleri pe ṣe laarin kilowaati mọkanla si marundinlogun ina solar ni a maa gbe si ori gbogbo orule laarin oṣu mọkanla."
Adebayo ni oun ti gbiyanju rẹ fun ilu oun nibi ti oun to ṣe idanilẹkọọ fun ẹgbẹrun meji eeyan nipa bi wọn ṣe n ṣe solar, oun yoo si ṣe bẹẹ fun Naijiria ti oun ba depo Aarẹ.
Ina ọba ko ni ṣẹju mọ - Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu
Oniruru ileri ni Aarẹ Tinubu ṣe faraalu lọdun 2023 to n du ipo Aarẹ.
Lara ileri rẹ ni pe ina ọba ko ni ṣeju mọ ti oun ba dori oye, koda, Tinubu sọ pe ki araalu ma dibo fun oun mọ ti oun ba kuna ninu ilera naa.
Amọ o ṣenu laanu pe ijọba to ṣeleri ina faraalu ti pada n lo sola bayii nile rẹ to wa ni Aso Rock, niluu Abuja.




























