Ìjọba àpapọ̀ fẹ́ máa fún àwọn ọmọ Naijiria tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ní 50,000 lóṣù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ Naijiria ti ṣe ifilọlẹ eto iranwọ oloṣooṣu kan, eyi ti wọn yoo ti maa fun awọn eeyan ti iṣẹ ati ọṣi n ba finra ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira loṣooṣu.
Eto iranwọ naa ni wọn lo wa fun lati mu igbesi aye rọrun fawọn ọmọ Naijiria.
Ki leto naa gan-an?
Atẹjade ti ileeṣẹ to n ri si fifi oju aanu wo ọmọniyan to si tun maa n ba wọn din ìṣẹ́ ku (Ministry of Humanitarian Affairs and Poverty Reduction) fi sita lọjọ Ẹti ana, ṣalaye pe ijọba yoo fun idile kọọkan ni aadọta ẹgbẹrun naira loṣooṣu.
Bii $37.14 owo dọla ni eyi.
Eto iranwọ yii kan National Emergency Relief and Stabilisation Intervention (NERSI) pẹlu.
Minisita fun eto iboju aanu wo ọmọniyan, Bernard Doro, ṣalaye pe say ijọba apapọ gbe eto yii kalẹ lati tete ran ọpọ ọmọ Naijiria lọwọ ni.
Doro sọ pe o tun wa fun lati ran wọn lọwọ nipa rira ounjẹ atawọn nnkan pataki mi-in.
Awọn wo ni yoo jẹ anfaani owo naa?
Pe o jẹ ọmọ Naijiria ko tumọ si pe iwọ tabi idile rẹ lẹtọọ si ẹgbẹrun lọna aadọta loṣu yii.
Eeyan ni lati kọkọ jẹ ẹni to wa nipo aini to si nilo owo naa gidi.
"Awọn ti yoo lẹtọọ si anfaani yii yoo gba ₦50,000 ($37.14) loṣu, eyi ti yoo jẹ iranwọ taara, ti yoo ran wọn lọwọ lati gbọ bukaata awọn nnkan to n mu igbesi aye nira fun wọn."
Minisita fun eto ifoju aanu wo ọmọniyan naa lo sọ bẹẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, wọn yoo maa ṣe agbeyẹwo owo naa loorekoore, ki wọn le maa ba bi nnkan ba ṣe n gbowo lori tabi walẹ lọja mu.
Doro fi kun un pe ijọba yoo fi to awọn to n jẹ anfaani naa leti ki wọn too ṣe ayipada kankan.
O ni awọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹka okoowo to ni iwe aṣẹ lori eto yii.
Ki otitọ le foju han, ki owo naa le tete de ọwọ awọn to nilo rẹ lai pẹ rara lo ni eyi ṣe n waye.
Bawo ni wọn yoo ṣe maa ri owo naa gba?
Atẹjiṣẹ ori aago ni Boro sọ pe yoo maa ta awọn eeyan lolobo bi owo naa ba wọle lati ọdọ awọn to n ṣeto rẹ.
O ni atẹjiṣẹ naa yoo beere pe ṣe ki oun sanwo naa si apo ikowosi wọn taara tabi omi-in ti a mọ si wallet.
Minisita naa sọ pe awọn ti yoo jẹ anfaani yii ko nilo iforukọsilẹ tabi sanwo sibikibi ki wọn too le kopa.
O rọ awọn ọmọ Naijiria lati ṣọra, ki wọn ma tibi eto iranwọ naa bọ si ọwọ awọn onijibiti.
" Ẹ ma ṣe sọ nọmba idanimọ yii (PIN) tabi ti banki (BVN) fun ẹnikẹni.
"Bi atẹjiṣẹ naa ba ru ọ loju, tabi bi ẹnikẹni ba beere owo lọwọ rẹ pe nọmba NERSI yii: 0700-022-2222."
Lara eto ireti ọtun (Renewed Hope) Aarẹ Tinubu ni eyi naa bi minisita iboju aanu woni ṣe sọ.
Eyi ni eto iranwọ kẹta ti Aarẹ Tinubu n ṣe laaarin oṣu kan ṣoṣo fun araalu.
Ninu oṣu Kẹwaa yii lo ṣeto ẹdinwo epo fun aadọrun ọjọ, lawọn ile epo NNPC.
Ẹgbẹrun lọna aadọrin (70,000) owo ọkọ loṣu lo ṣikeji, ko too kan aadọta ẹgbẹrun wayi fawọn alaini lati rọwọ mu lọ sẹnu.



