Ibi tí wọ́n bí mi sí kò jìnà síbi tí wọ́n ti ń ta igbó, àánú ló kó mi yọ tí mo fi di akọrin ẹ̀mí - Esther Igbekele

Àkọlé fídíò, Ibi tí wọ́n bí mi sí kò jìnà síbi tí wọ́n ti ń ta igbó, àánú ló kó mi yọ tí mo fi di akọrin ẹ̀mí - Esther Igbekele
Ibi tí wọ́n bí mi sí kò jìnà síbi tí wọ́n ti ń ta igbó, àánú ló kó mi yọ tí mo fi di akọrin ẹ̀mí - Esther Igbekele
Published

Gbajumọ akọrin ẹmi, Esther Igbekele, ti sọ pe ọpọ awọn akẹgbẹ oun ni ko fẹran iru orin toun n kọ.

Arabinrin Esther sọ fun BBC News Yoruba wi pe oju akọrin ẹmi to ti wọ inu aye lọpọ awọn akẹgbẹ oun maa fi n wo oun.

Igbekele ni''mi o le sọ pe awọn olorin ti a jọ n kọrin ko fẹran nnkan ti mo n ṣe.

Ṣugbọn kii ṣe bo ti yẹ ki wọn fifẹ han si nnkan ti mo n ṣe to ni wọn ṣe n ṣe.

Awọn ni wọn mọ idi ti wọn ko fi gbaruku ti mi, mo maa n ri omiran ninu wọn gan an to maa n sọ pe mo ti wọ inu aye pẹlu orin ti mo n kọ.

Mo si maa n dawọn lohun wi pe inu aye ni emi n gbe, aye si wa ninu aye; ati pe Ayeraye lo n ṣejọba aye.''