Àwọn ilé ẹ̀kọ́ tilẹ̀kùn wọn pa l'Osun nítorí ìròyìn pé agbébọn wọ ìlú, Adeleke ní kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀

Gomina Ademola Adeleke wọ buba ati fila nibi ipade ilu kan

Oríṣun àwòrán, X/@Osun_State_Gov

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti ke si awọn eeyan ipinlẹ naa pe ki wọn ma foya ki wọn ma si naani iroyin to n lọ ni igboro pe awọn agbesunmọmi ti wọle si ipinlẹ naa.

Adeleke lo sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan ti agbenusọ rẹ, Olawale Rasheed fi lede lọjọ Iṣẹgun.

Gomina ọhun sọ pe ayẹwo awọn ala ipinlẹ ọhun fi han pe ko si ijinigbe kankan nipinlẹ nibẹ, fun idi eyii, ki awọn eeyan ipinlẹ Osun ma foya ikọlu agbesunmọmi kankan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ọta ilu atawọn ọmọ ẹgbẹ alatako lo n gbe iroyin ẹlẹjẹ naa iri.

O ni "Mo rọ awọn eeyan ki wọn maa ba iṣẹ wọn lọ lai si ifoya kankan. Ijọba wa ti gbe awọn igbesẹ to yẹ lati daabo bo awọn ile ẹkọ wa.

"Ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ẹkọ atawọn ileeṣẹ ijọba to yẹ ti gbe igbesẹ idaabobo, a si ti n ṣiṣẹ lori rẹ."

Adeleke rọ awọn obi ki wọn ma foya nitori ọwọ awọn kọlọrọsi ẹda to fẹ da ipaya silẹ nipinlẹ naa ni iroyin ọhun ti wa.

O pari ọrọ rẹ pe gbogbo nnkan to yẹ ni ijọba oun yoo ṣe lati ri daju pe aabo to yẹ wa fun awọn akẹkọọ ati gbogbo olugbe ipinlẹ Osun.

Ọpọ ile ẹkọ ti ilẹkun wọn latari iroyin awọn agbesunmọmi

Ṣaaju ni ọpọ awọn ile ẹkọ ijọba ati ti aladani ti kọkọ ti ilẹkun wọn ni ijọba ibilẹ Odo Otin, Boripe, Osogbo ati Olorunda lẹyin iroyin pe awọn agbesunmọmi ti wọ ilu.

Lagbegbe Sasa, Oke Baale, ati ilu Osogbo, ọpọ awọn obi lo ya wọ ile ẹkọ lati lọ mu awọn ọmọ wọn pada sile ṣaaju aago mọkanla aarọ.

Bakan naa ni Eweta to wa ni Ikirun, ọpọ obi lo lọ mu awọn ọmọ wọn nile ẹkọ.

Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe agbegbe Ila Orogun ni iroyin ẹlẹjẹ nipa awọn agbesunmọmi naa ti kọkọ bu jade.

Gẹgẹ bi wọn ṣe jabọ, iroyin naa bẹrẹ lẹyin ti akẹkọọbinrin kan ko fẹ lọ sile ẹkọ.

Ki ni ọlọpaa sọ?

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti kin ọrọ gomina lẹyin ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, DSP Abiodun Ojelabi fi lede.

Ojelabi sọ pe irọ ni iroyin naa to n mi igboro titi, ati pe iwadii ọlọpaa fi han pe ko si ohun to jọ pe awọn agbesunmọmi wọ ilu tabi ṣọṣẹ nipinlẹ ọhun.

Lẹyin naa lo rọ awọn araalu ki wọn maa ṣe iwadii wọn daadaa ki wọn to maa pin iroyin kiri lori ayelujara.