Wo àwọn nǹkan márùn-ún tí o le fi dènà ọrùn dúndùn

Oríṣun àwòrán, BBC/Getty
- Author, David Cox
- Role, BBC Future
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Nigba ti a ba duro tabi ti jokoo, ori eeyan nikan maa n wọn ju kilogiraamu marun-un lọ gẹgẹ bi Anthony Ghosh, onimọ nipa ọpọlọ ati eegun ẹyin ni ile iwosan Queen's Hospital ati ileeṣẹ eto ilera ni London ṣe sọ.
Eyi kii ṣe ohun to buru rara gẹgẹ bo ṣe sọ amọ o dara lati ṣe amojuto ọrun ẹni nitori ọpọ eeyan, kaakiri agbaye, lo n ṣe awọn ohun to le mu inira ba ọrun wọn.
Ọpọlọpọ asiko ni a n lo lori foonu tabi niwaju ẹrọ kọmputa eyi to n mu ki a maa lo ọrun wa lọna aitọ, to si le mu ki ọrun maa dun eeyan ti eeyan ko ba tete mojuto.
Bi a ṣe maa n tẹ ọrun ti a ba n tẹ foonu maa n mu ki ẹru ti ori maa n gbe le ọrun le iwọn kilogiraamu mẹtadinlọgbọn gẹgẹ bi Ghosh ṣe sọ.
Ni kukuru, awọn igbe aye ode oni ko dara to fun ọrun wa ṣugbọn awọn nnkan marun-un wa ti eeyan le maa ṣe lati mu ki ọrun ẹni wa ni ilera pipe ni gbogbo igba lai fi ọjọ ori ṣe rara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Yiyi ọrun
Ọkan lara awọn ohun ti ileeṣẹ to n ri si eto ilera ni UK iyẹn NHS la kalẹ lati maa ṣe fun ilera ọrun ni yiyi ọrun.
Ti o ba wa lori ijokoo tabi ki o fi ẹyin sun silẹ, ki o yi ọrun si ẹgbẹ ọtun patapata ki o si duro sibẹ fun iṣẹju aaya diẹ.
Lẹyin naa ni wa a tun yi ọrun si ẹgbẹ osi fun iṣẹju aaya diẹ.
O le ṣe eyi ni ẹẹmeji si ẹẹmẹta ati iye igba to ba fi rọ ẹ lọrun si lojumọ.
- Gbigbe ọrun duro bo ṣe yẹ
Gbigbe ọrun duro bo ṣe yẹ ṣe pataki fun ilera ọrun nitori ti eeyan ko ba gbe ori duro bo ṣe tọ o le mu inira ba ọrun.
Ọrun eeyan gẹgẹ bi iṣẹda le yi kaakiri nitori naa o dara lati maa yi ọrun kaakiri ni ọpọ igba lojumọ.
Ọna to dara julọ lati ṣe eyi ni lati ri daju pe eeyan jokoo lai tẹ ẹyin tabi ti ori sẹyin pupọ.
O ṣe pataki lati ye maa bẹrẹ ori fun igba pipẹ paapaa ti eeyan ba n lo ẹrọ kọmputa, wo fiimu tabi wa ọkọ.
- Riri daju pe ọru wa ni ibamu pẹlu ejika
Jijokoo niwaju kọmputa fun igba pipẹ wa lara ohun to maa n ṣokunfa orun dundun.
Eyi maa n ṣẹlẹ lati bi eeyan ṣe maa n ti ori siwaju dipo ki ori wa ni ila kan naa pẹlu ejika.
Eeyan le ṣatunṣe eyi nipa fifi ọsan tabi bọọlu kekere si ijagbọn lojuna ati dena titẹ ọrun silẹ fun igba pipẹ.
- Mimu eegun ọrun le
Nitori bi a ṣe maa n lo ọpọ wakati ati niwaju kọmputa ati amohumaworan, to fi mọ foonu maa n jẹ ki a yi ọrun lọna ti ko tọ, Ghosh ṣalaye pe o maa n jẹ ki egungun to wa lọrun le lati gba ori duro.
Lati ṣe iranwọ fun egungun ọrun, sun si ẹyin rẹ, ki o ka orunkun rẹ ko, ki o si fi atẹlẹsẹ rẹ mejeeji lelẹ.
Lẹyin naa, ki o fi ọwọ rẹ si ẹyin ori rẹ, ki o gbe soke bii pe o fẹ ki ijagbọn rẹ kan aya rẹ.
Yọ ọwọ rẹ kuro lẹyin ori rẹ ki o si wa ni ipo yii fun igba diẹ ti agbara ba ṣe gbe.
O le wa ni ipo yii fun iṣẹju aaya ọgbọn tabi ju bẹẹ lọ.
- Jẹ ki yiyi ọrun rẹ mọ ọn lara
Ọna mii ti o fi le mu ki egungun ọrun rẹ wa ni ilera pipe ni lilo aga ati tabili.
Jokoo si ori aga ki o maa wo ọọkan rẹ ki o si maa gbe ọrun walẹ diẹdiẹ titi ti ijagbọn rẹ fi maa kan aya rẹ.
Wa nipo yii fun igba diẹ ki o to pada sipo ti o fi bẹrẹ.
Ṣe eyi fun iye igba ti o ba lagbara lati ṣe.
Ti o ba n ṣe awọn nnkan yii deedee, ọrun rẹ maa wa ni ilera pipe ni gbogbo igba.



























