Àwọn agùnbánirọ̀ tí wọ́n gba ìtúsílẹ̀ ti dé sí ìlú Ibadan

Awọn agunbanirọ naa, lasiko ti wọn gba itusilẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbogbo awọn agunbanirọ ti wọn jigbe nipinlẹ Imo, ṣugbọn ti wọn gba itusilẹ ni wọn ti de siluu Ibadan, ipinlẹ Oyo bayii.

Olu ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti a mọ si DSS, eyi to wa lagbegbe Aleshinloye nijọba ibilẹ Guusu-Iwọ-Oorun Ibadan ni wọn ko gbogbo awọn agunbanirọ ọhun lọ, ni kete ti wọn de siluu Ibadan.

Awọn agunbaniro ogun naa lo wa lara awọn ọgbọn ti wọn kuro niluu Ibadan, lati maa lọ si ipinlẹ Abia, nibi ti wọn yoo ti sin ilẹ baba wọn, ko to di pe awọn agbebọn da wọn lọna lopopona Owerri si Onitsha, iyẹn niluu Umunoha, ipinlẹ Imo.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, 2026 ni awọn agbebọn da awọn agunbanirọ naa lọna ninu bọọsi meji ọtọọtọ ti wọn fi n rin irin ajo.

Mẹwaa ninu awọn agunbanirọ naa ni wọn moribọ, nigba ti wọn sa asala fun ẹmi ara wọn ninu igbo, ti onikaluku wọn si gba inu igbo naa de ibi ti wọn n lọ.

Ọjọ meje gbako ni awọn agunbanirọ naa lo lahaamọ awọn agbebọn wọnyi, ko to di pe wọn lanfaani lati gba itusilẹ.

Ọjọru, ọsẹ yii ni awọn agunbanirọ ọhun de si ọgba awọn ọtẹlẹmuyẹ, ti awọn obi wọn si lọ sibẹ lati pade wọn.

Aṣoju awọn obi awọn agunbanirọ naa ni awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti a mọ si DSS yii gba laaye lati wọle sinu ọgba wọn, nigba ti awọn obi yooku duro siwaju ita.

Iroyin ti a gbọ ni pe miliọnu lọna aadọta naira ni awọn agbebọn naa n beere lọwọ mọlẹbi agunbanirọ kọọkan, ṣugbọn ti wọn pada fẹnuko lori miliọnu marun-un niara, ẹnikọọkan.

Olubadan kéde ìtúsílẹ̀ àwọn agùnbánirọ̀ ọ̀hún

Ninu awọn obi awọn agunbanirọ wọnyi ni wọn ti lọ rawọ ẹbẹ si Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja lati dide iranlọwọ, iyẹn lọjọ Abamẹta to kọja.

Latigba naa ni kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Abimbola ati Ọba Sefiu Adeyeri, Aseyin tiluu Iseyin naa ti dide lori ọna ti wọn yoo gba lati tu awọn agunbanirọ wọnyi silẹ lahaamọ awọn agbebọn.

Olubadan, Ọba Ladoja lo pada kede wi pe awọn agunbanirọ ọhun ti gba itusilẹ, iyẹn lẹyin to ti ri ẹri gba lọdọ Gomina Hope Uzodinma ti ipinlẹ Imo.

"Awọn agunbanirọ ti wọn jigbe naa ti ri itusilẹ gba. Gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma, lo fidi rẹ mulẹ fun mi lasiko ti a jọ sọrọ lori foonu ni nnkan bi agogo marun-un irọlẹ," Ladoja sọ bẹẹ ninu atẹjade ti Adeola Oloko to jẹ agbẹnusọ rẹ fi lede.