World Cup: ikọ̀ Spain náà ti dagbére fún Russia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Published
Ìyàlẹ́nu jùlọ lọ̀rọ̀ ọ̀hún jẹ́ fún gbogbo olólùfẹ́ bọọlù nínú ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó lọ lọ́wọ́ bí ní Orílẹ̀-èdè Russia se lé Spain tó gba ife lọdun 2010 kúro ninu ìdíje ọdún 2018.
Wọn na Spain fún igba àkọkọ ni ọdun méjìdinláàdọ́ọta sẹyìn ninu wòmi-ń-gba-sí ọ láti wo ipele kòmẹsẹ yọ.
Lẹ́yìn ti wọn lo àkoko wọn tan tí ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù méjèèjì ni ọ̀ọ̀mi ayò kan ní wọn ba fi wòmi-ń-gba-sí ọ mọ ẹni ti yóò dúró àti ẹni tí yóò lọlé



















