Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ikéde ìjọba láti mú ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ wálẹ̀ láàárín àádọ́rùn ún ójọ́

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ Naijiria ti ṣi aṣọ loju eto kan ti wọn sọ pe yoo maye dẹrun faraalu laarin aadọrun ọjọ.

Eto naa ti wọn pe ni "90-Day Action Plan To Ease Cost Of Living For Nigerians" ni ijọba buwọlu nibi ipade ilu kan to waye niluu Abuja, ti igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima tukọ rẹ.

Laari aadọrun ọjọ naa ni wọn ni nnkan yoo dẹrun nipa bi ọwọngogo ounjẹ ati owo ọkọ yoo ṣe walẹ.

Eto naa lo jẹ ọkan lara awọn aba ti minisita fun eto inawo, Taiwo Oyedele daba rẹ nibi ipade ọhun to waye lori ayelujara.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, afojusun eto naa ni lati mu ko rọrun faraalu lati ra ounjẹ, mimu owo ori sisan rọrun, iranlọwọ fun awọn idile, ti tete pari awọn akanṣẹ to kan araalu gbọngbọn ati mimu iṣoro ti awọn oludokoowo maa n koju ni Naijiria kuro.

Agbẹnusọ Aarẹ Tinubu, Stanley Nkwocha, lo fi alaye naa lede.

Amọ ṣa, awọn eeyan kan ti n sọ pe kii ṣe nitori ifẹ araalu ni ijọba ṣe kede ato naa, amọ o kede rẹ ki awọn eeyan le dibo fun Aarẹ Bola Tinubu fun saa keji ni.

Ki eredi ti ijọba ṣe gbe eto yii kalẹ?

Igbimọ ijọba nibi ipade naa pẹlu igabkeji Aarẹ Kashim Shettima

Ijọba ni eto naa n waye lati di alafo to wa laarin igbiynaju ijọba lori eto ọrọ aje Naijiria ati imọlara rẹ lara awọn araalu.

Ti ẹ ko ba gbagbe, bo tilẹ jẹ pe ijọba sọ pe oun n ṣe awọn nnkan tuntun ki eto ọrọ aje Naijiria le dara, ọpọ araalu lo n sọ pe awọn ko ni imọlara rẹ ninu igbeaye wọn.

Nigba to n sọrọ nibi ipade ilu naa, Shettima sọ fun awọn gomina pe ki wọn jẹ ki awọn eeyan ipinlẹ wọn ni imọlara awọn eto ijọba lara wọn.

O ni eto ti oun n ṣe gbọdọ parada si owo mọto ti ko ga ju agbara araalu lọ, eto ilera to peye, ipese iṣẹ ati owo ninu apo araalu.

Ṣe owo ounjẹ yoo walẹ?

Bo tilẹ jẹ pe wiwalẹ owo ounjẹ ni ọkan gboogi lara afojusun eto naa, ijọba ko fidi rẹ mulẹ pe owo ounjẹ yoo ja walẹ laarin aadọrun ọjọ ti eto naa yoo fi waye.

Ikede ijọba ṣe ko mẹnuba koko awọn ohun ti ijọba yoo ṣe, iye owo to la kalẹ fun eto naa ati iye ida owo ounjẹ ti yoo walẹ.

Amọ ṣa, ọpọ lo gbagbọ pe o ṣeeṣe ki ounjẹ walẹ ti owo ọkọ ba le wa silẹ.

Ti owo ọkọ ba wa silẹ ti awọn agbẹ ba si ri iranlọwọ gba lọwọ ijọba, yoo mu ayipada rere ba iye owo ounjẹ amọ ijọba ko mẹnuba eyii ninu ikede rẹ.

Ṣe owo ọkọ yoo walẹ?

Nibi ipade naa, wọn fẹnuko pe ijọba apapọ, ni ifọwọsowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ yoo ṣagbatẹru bi wọn yoo sẹ ko awọn ọkọ to n lo gaasi CNG ati ina ẹlẹtiriki wọle ki lilọ-bibọ araalu le rọrun fun wọn.

Wọn paṣẹ fun awon ti ọrọ kan lati ba awọn adari ẹgbẹ awakọ sọrọ lori bi wọn yoo ṣe din owo ọkọ ku pẹlu lilo awọn ọkọ ẹlẹtiriki ati CNG naa.

Amọ awọn onimọ ti sọ pe lilo ọkọ CNG ko tumọ si pe owo ọkọ yoo dede ja walẹ nitori awọn nnkan mii rọ mọ bii iye owo awọn elo ara ọkọ ati bi yoo ṣe rọrun fun awọn awakọ lati ri gaasi CNG naa ra.

Ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin aadọrin ọjọ ti ijọba kede?

Igbimọ ijọba nibi ipade naa pẹlu igabkeji Aarẹ Kashim Shettima

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ko mẹnuba ọjọ pato ti eto naa yoo bẹrẹ, ti ijọba ba bẹrẹ igbesẹ naa lọjọ kejilelogun oṣu Kẹwaa to kede eto naa, o n tumọ si pe ogunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2027 ni eto ọhun yoo pari.

Ohun ti araalu yoo maa reti ni ki ijọba kede aṣeyọri eto naa ati ayipada to de ba iye owo ounjẹ ninu ọja.

Ju gbogbo rẹ lọ, ohun ti yoo sọ boya eto naa ṣaṣeyọri tabi bẹẹ kọ ni ti awọn araalu ba ri ayipada rere ninu igbesi aye wọn ati iye ti wọn n na ninu ọja.