Àdó olóró ológun òfurufú tí wọ́n ló pa ọ̀pọ̀ aráàlú nínú ọjà ní Yobe, ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, NAF
Ọpọ eeyan ti wọn jẹ araalu ni iroyin sọ pe wọn ti balẹ sile iwosan bayii, latari ifarapa ti wọn ni lasiko ti ado oloro awọn ọmọ ogun ofurufu Naijiria, Nigerian Air Force, (NAF) ṣọlẹ sibi ti wọn ti n naja nirọlẹ ọjọ Abamẹta.
Koda, yatọ si awọn to farapa, a gbọ pe eeyan to le ni ogun (20) lo tun di oloogbe ninu iṣẹlẹ ojiji naa.
Ọja kan ti a mọ si Jilli, to gbajugbaja to si jẹ aala ipinlẹ Yobe ati Borno ni iṣẹlẹ yii ti waye.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Yobe, Dungus Abdulkarim, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun ẹka iroyin The Punch.
O ni o ṣẹlẹ ni Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii, amọ awon ko ti i le sọ iye eeyan to fara kaaṣa bayii.
Ọja Jilli ko jinna si abule Fuchimiram, nijọba ibilẹ Geidam , ipinlẹ Yobe.
Ilu Jilli paala pẹlu Damasak ni Borno.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Ohun ti a gbọ ni pe ikọ ologun oju ofurufu naa n dọdẹ awọn agbesunmọmi Boko Haram to n daamu agbegbe naa ni wahala yii fi ṣẹlẹ.
Iroyin kan sọ pe awọn Boko Haram maa n wa si ọja Jilli lati daamu awọn eeyan, wọn yoo si tun gba owo ilẹ ati ọja lọwọ wọn pẹlu.
Ọja Jilli yii ni wọn lo tobi to bẹẹ ti awọn eeyan maa n waa na an lati Giedam ni Yobe, Gubio, agbegbe Chibok ati Benisheikh ni Borno.
Eyi lo mu ikọ ologun NAF gbiyanju lati mu awọn Boko Haram naa balẹ lasiko ti ikọ ologun naa n rin lofurufu, ti wọn si ti oju ofurufu ṣina bole .
Awọn eeyan kan sọ pe o kere tan, eeyan mẹwaa lo ba iṣẹlẹ yii rin, nigba ti ọpọ eeyan farapa.
Awọn oṣiṣẹ eleto ilera pajawiri ti wa nibudo naa lẹyin iṣẹlẹ, awọn to farapa si ti n gba itọju lawọn ile iwosan ni Giedam ati Damaturu ti I ṣe olu ilu ipinlẹ Yobe gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Tẹ o ba gbagbe, eyi kọ ni igba akọkọ ti ologun oju ofurufu Naijiria yoo ṣeṣi ju ado oloro si araalu.
Ileeṣẹ ologun NAF fidi ẹ mulẹ pe oun gbe igbese atunṣe ni Jilli ati agbegbe rẹ
Ninu atẹjade kan ti Adari ikede NAF, Air Commodore Ehimen Ejodame, fi sita ni NAF ti sọ pe oun ṣe itẹsiwaju atunṣe agbegbe naa, nitori awon agbesunmomi to n da ibẹ laamu.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ boya igbese naa mu ijamba dani.
Wọn ni ọjọ kọkanla oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni igbesẹ naa waye ni Jilli ati agbegbe rẹ.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe wi, igbesẹ ọhun wa ni ibamu pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ologun ori ilẹ ti a mọ si Operation HADIN KAI, nibi ti wọn ti n dọdẹ awọn agbesunmọmi.
Wọn fi kun un pe igbesẹ naa waye lati le awọn agbesunọmi to ba ṣẹku danu, ko si tun le jẹ itẹsiwaju aṣeyọri fun ileeṣẹ ologun ilẹ wa.
Ati lati le so okun aabo le si I pẹlu ni awọn agbegbe to lewu bii ipinlẹ Borno ati Ariwa Ila Oorun Naijiria .
Ṣugbọn atẹjade NAF ko sọ boya igbesẹ naa mu ipalara tabi gba ẹmi araalu lọwọ.
Wo ìgbà mẹ́fà ọ̀tọ̀tọ̀ tí ọkọ̀ òfúfurú ọmọ ogun Nàìjíríà ti ṣèṣì ju àdó olóró sí aráàlú
Oṣu kinni, ọdun 2023
Ko din ni eeyan mẹtadinlaadọta to jade laye lagbege Rukubi, nipinlẹ Nasarawa, nigba ti ado oloro ileeṣẹ ọmọ ogun balẹ sibẹ.
Agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye sunmọ ala ilẹ ipinlẹ Benue ati Nasarawa.
Oṣu Keji ọdun 2022
Ninu oṣu keji, ọdun 2022 ni ọkọ ofurufu ọmọ ogun Naijiria ṣekupa ọmọde meje, ti ọpọ eeyan mii si farapa lorilẹ-ede Niger.
Iroyin ni awọn janduklu ni ikọlu naa dojukọ amọ awọn araalu ba a lọ.
Oṣu kejila, ọdun 2022
Ninu oṣu Kejila ọdun ni ado oloro ọmọ ogun Naijiria ṣekupa eeyan mẹrinlelọgọta ni ilu Mutumji, ni ijọba ibilẹ Zamfara.
Awọn eeyan to wa nibẹ sọ pe pupọ lara awọn to ku lo jẹ janduku amọ ọpọ araalu naa jade laye ninu ikọlu ọhun.
Lara awọn to ku ni obinrin atawọn ọmọde wa.
Oṣu Kẹfa, ọdun 2022
Ileeṣẹ ọmọ ogun sọ nigba naa pe awọn janduku loun n dojukọ ogun naa kọ, kii ṣe araalu.
Agọ awọn janduku ni awọn ọmọ ogun n doju ija kọ ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ko to ṣẹṣi pa awọn araalu.
Abule Kunkuna, nijọba ibilẹ Safana to wa ni ipinlẹ Katsina ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Ọpọ eeyan lo jade laye nibẹ.
Ọdun Kẹrin 2021
Ọkọ ofurufu ọmọ ogun kan to n lọ koju ikọ Boko Haram ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ṣeṣi sọ ado oloro si awọn akẹgbẹ rẹ.
Iroyin ni ko din ni ogun (20) ọmọ ogun to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
Oṣu Kẹsan an, ọdun 2021
Ninu oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 kan na, ọkọ ofurufu ọmọ ogun Naijiria ju ado oloro si aarin abule kan ni ijọba ibilẹ Yunusari, nipinlẹ Yobe.
Eeyan mẹwaa lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

























