Wo àkóbá mọ́kànlá tí ohun mímu ‘Energy Drinks’ le ṣe fún àgọ́ ara rẹ
Oniruuru ohun mimu lo wa lori atẹ eyi ti tọmọde tagba fi n rẹ oungbẹ.
Ọkan ninu wọn ni ohun mimu ẹlẹrindodo to wa fun alekun agbara ti ọpọ eeyan mọ si 'Energy Drinks'.
Aarin awọn ọdọ ilẹ wa ohun mimu amusagbara yii ti wọpọ, ti wọn si le mu agolo meji si mẹta ni ojumọ.
Awọn eroja ohun mimu amusagbara yii si lo ni eroja Caffein ninu, eyi to lewu pupọ fun agọ ara ẹni
Sugbọn ọpọ awọn ọdọ yii ni ko mọ awọn ewu to rọ mọ ohum mimu amusagbara naa.
Idi si ree ti BBC News Yoruba fi se fidio yii lati la awọn eeyan lọyẹ lori awọn akoba to wa ninu mimu ohun mimuẹlẹrindodo fun amusagbara.

Eroja mẹsan-an to wa ninu ohun mimu ẹlẹrindodo Energy Drinks
Awọn ohun mimu ẹlẹrindodo fun amusagbara ni ọpọ eroja ninu, ti ohun mimu naa si wa ninu ike ati agolo lori atẹ.
Lara ipolowo ti wọn si maa n se lati ta awọn ohun mimu alagolo naa ni pe o maa n fun ni lokun ati agbara lati le mu ka sisẹ ju bo se yẹ lọ.
Ọpọ awọn akẹkọọ si lo maa n mu lati fi kawe tabi sisẹ agbara, koda, awọn mii ti ko fẹ mu ọti lile maa n gba lati mu Energy Drinks fi rẹ oungbẹ.
Awọn eroja to si wa ninu awọn ohun mimu amusagbara naa niwọnyi:
Caffein
Trouley
Vitamin B1
Vitamin B2
Vitamin B3
Vitamin B5
Vitamin B6
Vitamin B7
Vitamin B12
Akoba mọkanla ti mimu ẹlẹrindodo Energy Drinks fun amusagbara n se lagọ ara
Ọpọ iwadii ijinlẹ lẹka imọ isegun lo ti se afihan diẹ lara awọn akoba ti mimu ohun mimu ẹlẹrindodo fun amusagbara n se fun agọ ara ẹni to ba n mu u nigba gbogbo.
- Apọju eroja suga to le fa ewu fun ọpọlọ, ti yoo si jẹ ki onitọun maa gbagbe nnkan eyi ti oloyinbo n pe ni Inflammation
- Energy Drinks tun le se okunfa ifunpa giga tabi ki ọkan rẹ maa mi hẹlẹhẹlẹ ju bo se yẹ lọ
- Airi oorun sun lasiko
- Aini isinmi ninu ọpọlọ ẹni
- Apọju eroja Suga le gbẹnu soke ninu ẹjẹ
- Apọju itọ titọ ni isẹju-isẹju
- Igbẹ Ọrin to le jẹ ki omi ara gbẹ
- Ijamba fun kindinrin ninu agọ ara
- Ki eeyan sanra si
- Mimu ebi pa ni loore-koore
- Ki oungbẹ maa gbẹ ni loore koore.
A wa n gba awọn ọdọ nimọran lati sọra fawọn eroja ohun mimu ẹlẹrindodo Energy Drinks.
Tabi awọ́n eroja ohun mimu miran to ni ẹroja Caffein ninu nitori ti wahala to wa ninu rẹ ba delẹ tan, apa rẹ le ma ka.






