Bílíọ̀nù mẹ́jọ Naira làwọn ajínigbé ti gbà lọ́wọ́ aráàlú láàrín ọdún 2025 sí 2026 - Ìwádìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ajinigbe ti gba owo to din diẹ ni miliọnu mẹfa dọla owo ilẹ Amẹrika laarin ọdun kan sẹyin.
Gẹgẹbi iwadii kan ti ileeṣẹ kan, SBM Intelligence to n ri si ọrọ abo ati ọtẹlẹmuyẹ ṣe sọ niyi.
Iwadii ajọ naa sọ pe eeyan ẹgbẹrun meje o le ẹgbẹrin ati marundinlọgbọn (7, 825)ni awọn ajinigbe ti ji gbe laarin oṣu keje ọdun 2025 si oṣu kẹfa ọdun 2026, eyi jẹ alekun ida mẹrindinlaadọrin ninu ọgọrun, (66%) si ti ọdun to kọja. Ko din ni ẹgbẹrun kan o le ogoje ati meji (1, 142) eeyan ti wọn pa laarin akoko naa ti iye owo itusilẹ tawọn ajinigbe si gba, eleyi to han sita jẹ biliọnu mẹjọ din diẹ naira (N7.78bn)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ SBM to kede iwadii yii sọ pe awọn iye owo ti o n jade ninu iroyin, ifọrọwerọ ita gbangba atawọn iroyin miran to han si araalu lawọn tọka si ninu rẹ. Bẹẹni wọn ni o ṣeeṣe ki iye owo naa nitootọ pọ ju eyi lọ nitori pe awọn miran wa ti wọn ko kede sita faye gbọn.
Ileeṣẹ iroyin BBC ti kan sawọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun lati tan imọlẹ si ọrọ yii.
Nigbakan ri awọn agbegbe ti awọn agbesunmọmi ti n ṣọṣẹ lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria ti wa tan kalẹ gbogbo ẹkun iwọ oorun ariwa ati aringbungbun ariwa orilẹede Naijiria bayii nibi ti awọn janduku ti wọn n pe ni agbebọn lọpọ igba ti n kọlu awọn ileto kekeke awọn opopona atawọn ileẹkọ nibẹ.
Ki ni iwadii wọn sọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ SBM ni iye awọn ikọlu ijinigbe to ti waye lẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria ti le si ni iwọn ida mejidinlọgọrin ninu ọgọrun (78%) ni abala akọkọ ọdun yii.
Ninu iwadii rẹ, o ni ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Boko Haram lo gba ida aadọrun (90%) awọn owo itusilẹ ti wọn kọ silẹ lẹkun ila oorun Ariwa, bi o tilẹ jẹ wi pe iṣẹlẹ ijinigbe atawọn ti wọn ji gbe pọ ju tiwọn lọ lẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria.
Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn ologun atawọn ileeṣẹ alaabo gbogbo ti tubọ n tẹmpẹlẹ mọ igbogun ti awọn ajinigbe ati agbebọn ti wọn si n tu awọn ti wọn ji gbe silẹ lọgọọrọ, sibẹ ijinigbe lọpọ yanturu ṣi n lọ sii.
Ki lawọ̀n igbesẹ awọn ileeṣẹ alaabo lẹnu lọwọlọwọ yii?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni oṣu kẹjọ, awọn ileeṣẹ alaabo tu ọdunrun o le mẹjọ eeyan silẹ lọwọ awọn ajinigbe kaakiri ipinlẹ Kwara ati Niger. Ko si ẹni le sọ boya wọn san owo itusilẹ fun eyi.
Loṣu kọkanla, ọọdunrun o le marundinlogun akẹkọọ ati awọn olukọ ile ẹkọ St Mary's Catholic School ni Pipiri ni ipinlẹ Niger wa lara awọn tawọn agbofinro tu silẹ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ilu le, oniruuru igbesẹ lawọn mọlẹbi awọn ti wọn ba ji gbe maa n wa lati wa ọna tu awọn eeyan wọn silẹ lọwọ awọn ajinigbe. Ninu ọna ti wọn n gba naa ni sisare kijokijo lati wa owo jọ fi gba itusilẹ wọn bi o tilẹ jẹ wi pe ofin Naijiria ko faye gba sisan owo itusilẹ fun awọn ajinigbe.
























