You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Agbébọn kọlù ibùdó ọlọ́pàá ní Kwara yìnbọn pa mẹ́ta, méjì mii farapa
Awọn agbebọn ti wọn n ṣọsẹ ni ijọba ibilẹ Kaiama, ni apa ariwa ipinlẹ Kwara ko tii dẹkun isẹ ibi wọn.
Ṣe ni wọn tun ya wọ ibudo awọn ọlọpaa ni ilu Tenebo nibi ti wọn ti ṣekupa ọlọpaa mẹta nigba ti meji mii tun farapa.
Olugbe agbegbe ilu naa kan to sọ pe ki a fi orukọ bo oun laṣiri ṣalaye fun BBC Yoruba pe lati irọlẹ ọjọ Ẹti ni awọn araalu ti fura pe wọn ti wọlu.
O ni "Bi awọn agbebọn naa ṣe n gbe alupupu wọn kọja lọ si ilu Tenebo ni awọn ara ilu ti wọn gba kọja ti ri wọn, ti wọn si n woye ilu ti wọn tun ti n lọ ṣe akọlu si.
"Igba ti wọn rii pe ọna Tenebo ni wọn gba lọ, wọn ransẹ si wọn ki wọn gbaradi nitori awọn ti wọn ri ti wọn kọja lọ si ilu wọn.
"Lori ọrọ yii ni awọn ọdẹ fi pe ara wọn jọ, wọn si tun fi to awọn ọlọpaa Moba ti wọn n sọ agbegbe naa leti.
"Gbogbo awọn ẹṣọ alaabo yii ni wọn jọ ṣisẹ papọ ti wọn si n wa awọn onisẹ ibi yii kaakiri inu ilu.
"Igba ti wọn wa wọn di bii ago mẹwaa alẹ ti wọn o kofiri wọn ni olukaluku pada si ibuba rẹ amọ, pẹlu igbaradi."
Araalu naa tẹsiwaju pe inu igbo lẹba ilu naa ni awọn agbesunmọmi yii farapamọ si, ti wọn si n pete-pero ati ṣe akọlu ti wọn wa se.
O ni "Bi wọn ṣe wọle ni wọn lọ taara si ibudo awọn ọlọpaa, wọn si sina ibọn bolẹ nibẹ.
"Ki Olorun gba wa lọwọ, awọn ti wọn n dọdẹ wa, lotitọ ni awọn ọlọpaa ti fura pe o ṣeeṣe ki wọn ti wa ninu ilu, amọ ko si ẹni to le sọ ibi ti wọn yoo gba yọ.
"Ibọn ba awọn ọlọpaa mẹta, nigba ti awọn iyoku ṣee ni mọja-mọsa.
"Awọn ọlọpaa iyoku fẹsẹfẹ sugbọn wọn pada wa laipẹ lati koju wọn.
"Bi awọn ọlọpaa ṣe n yinbọn naa ni awọn ọlọdẹ naa n yin ti wọn.
Àwọn agbébọn júbà ehoro nígbà tí ipá wọn pin
Araalu naa tẹsiwaju pe igba to di pe ija naa le, awọn agbebọn ọhun sa lọ latari pe ibọn awọn ọdẹ ati ti awọn ọlọpaa o jẹ ki wọn le duro ṣe ohun ti wọn wa se.
O fi kun pe awọn agbebọn naa pọ ti wọn wa pẹlu alupupu amọ oun o le sọ ni pato iye ti wọn jẹ.
Lẹyin ibeere lori ohun ti awọn agbebọn naa wa se ninu ilu, olugbe naa sọ pe, ohun ti oun ro ni pe wọn wa lati pa awọn araalu ati lati ji awọn eeyan ko lọ gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe ni Wọrọ ninu osu keji ọdun 2026 yii.
O sọ pe "Ohun ti wọn fẹ maa se bayii ni yẹn, ki wọn wọ ilu, pa awọn eniyan nipakupa, ki wọn si tun ji ọpọ gbe sa lọ.
"Amọ wọn o ri iyẹn ṣe mọ nitori pe gbogbo ilu ni wọn ti gbaradi bayii. Ko si ilu to fẹ ki irufẹ ikọlu Woro sẹlẹ si oun.
"Nitori titi di isinsinyii, awọn ti wọn ji ko lọ ni Woro o tii gba ominira.
Ohun tí ọlọ́pàá Kwara sọ
Ninu atẹjade kan, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Adetoun Ejire-Adeyemi sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyii to da omi tutu sọkan awọn.
Atẹjade ọhun sọ pe "Ikọlu buruku yii gbẹmi ọlọpaa mẹta, bẹẹ ni ọpọ awọn mii tun farapa... a ko ni gbagbe ifaraẹni jin awọn ọlọpaa to padanu ẹmi wọn lailai."
Lẹyin naa lo ba mọlẹbi awọn ọlọpaa ti wọn padanu ẹmi wọn ọhun kẹdun pẹlu adura pe ki awọn ti wọn farapa tete gbadun.
O pari atẹjade naa pẹlu ileri pe kọmiṣọna ọlọpaa, Ojo Adekimi yoo da awọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa sinnu igbo lati ṣawari awọn to ṣiṣẹ ibi naa, ati pe wọn ko ni lọ lai jiya ohun ti wọn ṣe.