Peter Obi fi ẹgbẹ́ òṣèlú ADC sílẹ̀, ṣàlàyé èrèdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour ninu eto idibo ọdun 2023 ti kede pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn iṣoro abẹle to n ba ẹgbẹ ọhun finra lo jẹ ki oun kuro nibẹ.

Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade ti Obi fi lede loju opo X rẹ lọjọ Aiku.

Ninu atẹjade naa, o mẹnuba bi eto oṣelu Naijiria ṣe buru to, ati bi awọn araalu ṣe maa n gbogun ti awọn gbajumọ lawujọ.

O ni oun ko fi ẹgbẹ oṣelu ADC silẹ latari ẹtanu pẹlu awọn eekan inu ẹgbẹ ọhun bii alaga rẹ, David Mark, tabi igbakeji Aarẹ Naijiria rẹlẹ, Atiku Abubakar.

Peter Obi ṣalaye pe rogbodiyan inu ẹgbẹ ADC, eyii to n farajọ ohun toun dojukọ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour lo mu oun fi ẹgbẹ naa silẹ.

Gomina ipinlẹ Anambra nigba kan ri naa sọ pe "Awọn alagbara Naijiria kan ti wọn da rogbodiyan abẹle silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour ti mo fi kuro ninu ẹgbẹ ọhun tun ti n wọ inu ẹgbẹ oṣelu ADC."

O mẹnuba bi oniruru igbẹjọ to n waye lemọlemọ, ipinyna laarin awọn ọmọ ẹgbẹ, bi awọn ọmọ ẹgbẹ ṣe n fura si ara wọn ṣe n mu oju ẹgbẹ naa kuro ninu ohun to yẹ ko gbajumọ.

Ninu ọrọ rẹ, o tun ṣalaye pe awọn eeyen n wo otitọ ṣiṣẹ ati iwa irẹlẹ gẹgẹ bii iwa ojo, ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu ẹnikẹni to ba fẹ ṣe ohun to tọ ati ati eyii to yẹ.

Obi ni "Koda, laarin ibi ti eeyan ti n ṣiṣẹ takuntakun, wọn n ṣe onitọhun gẹgẹ bii alejo."

O tẹsiwaju pe oun atawọn alatilẹyin ni lawọn eeyan maa n sọ oko ọrọ si bo tilẹ jẹ pe wọn m gbiyanju tiwọn ki nnkan le dara.

O tẹsiwaju pe oun ko du ipo Aarẹ nitori oun n wa agbara, bikoṣe pe oun n wa orilẹede ti ara yoo ti tu gbogbo mutumuwa.

"Mi o fi tipatipa sọ pe mo fẹ di Aarẹ, igbakeji Aarẹ tabi agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin, ohun to ka mi lara ni orilẹede ti gbogbo nnkan yoo ti dẹrun fun gbogbo araalu."

Obi ko mẹnuba inu ẹgbẹ mii to n lọ bayii amọ o ti sọ pe bo tilẹ jẹ oun ti fi ADC silẹ, ohun to jẹ oun logun ni ki Naijiria dara.