Lisabi 2026: Wo bí àwọn ọmọ Abeokuta ṣe dábírà níbi ayẹyẹ ìrántí akọni wọn
Awon akọni pọ nilẹ Yoruba ti awon eeyan ṣi n ṣeranti titi di oni, ọkan lara won ni Lisabi Agbongbo Akala ti awon ọmọ ilu Abeokuta ki i fi ṣere rara.
Lasiko ti ogun Oyo n ja awon eeyan Ẹgba ni Lisabi ṣaaju ogun fun won, ni nnkan bii Senturi kejidinlogun si asiko yii, to si gba won lọwọ ijẹgaba awọn eeyan naa.
Lati igba naa ni awon ọmọ Egba ti n yẹ akọni to gba won kalẹ naa si, ti won n fi ọdọọdun ṣe iranti rẹ lọna ara.
Fun ti ọdun 2026 to waye laipẹ yii kaakiri Abeokuta, kari ibi gbogbo ti awon omo Egba wa ni won ti wale lati ṣe ọdun naa.
Oniruuru aṣọ ni won fi dara nibi eto naa ti won tun pe ni Egbaliganza, Kabiyesi Alake, Ọba Gbadebo Aremu (Okukenu kẹrin wa nikalẹ, titi kan Senetọ Ibikunle Amosun to fi figba kan jẹ gomina Ogun ri, awon eler ori itage, awon oniṣowo nla nla ọmọ ilẹ Egba ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Wọn fi idunnu wọn han, pẹlu alaye pe awọn mọ riri oore ti Lisabi ṣe fawọn bo ti wu ko ti pẹ to, awon ko si ni i yee ṣe iranti rẹ titi kan Sodeke atawọn akọni Egba yoku pata.





