Ọbalayé tó kéré jùlọ lágbáyé jáde láyé lẹ́ni ọdún 34

Aworan ọba Oyo Nyimba Kabamba Iguru Rukidi Kẹrin.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọba alaye kan ni orilẹede Uganda ti wọn pe ni ọbalaye to kere julọ lagbaye ti jade laye lẹni ọdun mẹrinlelọgbọn.

Bashọrun ilu rẹ, to kede iku ọbalaye naa, ni Oyo Nyimba Kabamba Iguru Rukidi Kẹrin gun ori itẹ ọba ilu Tooro lẹkun iwọ oorun orilẹede Uganda nigba to jẹ ọmọ ọdun mẹta pere nigba ti baba rẹ ku lọdun 1995.

Ilu Toroo ko sọ ohun to ṣokunfa iku ọbalaye naa, amọṣa minisita kan ni ijọba orilẹede Uganda ṣalaye lori ileeṣẹ iroyin abẹle kan lorilẹede naa pe o ṣaarẹ to lagbara gidigidi tobẹẹ gẹ to jẹ wi pe orilẹede Amẹrika lo wa itọju lọ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe aarẹ alagbada lo n ṣakoso ijọba lorilẹede Uganda, amọṣa o ni awọn ilu kaakiri ti wọn ṣi n tẹsiwaju pẹlu ilana ibilẹ wọn.

Ajọ Guinness World Records ṣe akọsilẹ orukọ Oyo gẹgẹbi ọbalaye to kere julọ lagbaye. O si n ṣakoso le awọn eeyan to le ni miliọnu meji lori. Oun si ni ọba kẹtala ti yoo jẹ ni ilu naa.

Nigba to ba n kede iku rẹ lọjọbọ, igbakeji ọbalaye naa, Calvin Armstrong Rwomiire Akiiki ṣapejuwe iku rẹ gẹgẹbi "ọfọ nla" si ile ọba ilu Tooro.

Ni ilu Tooro, oye atirandiran ni ipo ọba ilu naa. Oyo ko ni iyawo nigba aye rẹ, niwọn ba ohun to han si araalu nipa igbesi aye rẹ, awọn Akiiki sọ pe ko si wahala kankan nipa ẹni ti yoo gun ori oye naa lẹyin ipapoda rẹ.

Nigba to de ori oye ni ọdun 1995, wọn yan awọn adeleọba ninu eyi ti iya rẹ wa lati maa ṣe iranlọwọ pẹlu akoso titi di igba ti Oyo ba pe ọdun mejidinlogun ti wọn ṣe eto igbade rẹ.