Àwọn ọmọ Iran kọminú lórí bóyá ogun Amẹ́ríkà lè tẹ̀síwájú tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ lẹ́yìn tí ìpàdé àláfíà forí ṣánpọ́n

Awọn ọkọ ati alupupu to n kọja niwaju aworan adarimIran tuntun, Mojtaba Khamenei

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Ghoncheh Habibiazad
    • Role, Senior reporter, BBC News Persian
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ibaṣepọ ti ko dan mọran to wa laarin Iran ati Amẹrika tubọ buru siwaju si lẹyin ti ipade alaafia laarin orilẹede mejeji to waye ni Pakistan lulẹ.

Ileeṣẹ ọmọ ogun Amẹrika sọ pe oun yoo bẹgi dina oju ọna ti ọkọ agbepo Iran n gba kọja nigba ti Iran naa dunkoko pe oun yoo gbogun ti awọn orilẹede Gulf to n ṣatilẹyin fun Amẹrika layika oun.

Ọrọ naa ti da ibẹrubojo sọkan awọn eeyan Iran bayii pẹlu ibẹru pe ado oloro tun le pada maa rọ le awọn lori.

Ọkunrin ẹni ogun kan niluu Karaj, to sunmọ Tehran sọ fun awọn akọroyin pe "mo tilẹ ro pe wọn maa fẹnuko lati da ogun naa duro ni.

"Mo gbagbọ pe ogun naa yoo tun pada bẹrẹ lọla tabi lọsẹ to n bọ tabi lọjo mii laipẹ."

Ninu iran, ijọba ti gbe oju opo ayelujara tipa lati nnkan bii ọsẹ mẹfa sẹyin, eyii to mu ko nira fun awọn araalu lati kan si awọn mọlẹbi wọn.

Ijọba orilẹede naa sọ pe eredi igbesẹ ọhun ni lati dena ikọlu si awọn lati ori ayelujara.

BBC News Persian, to jẹ ẹka ileeṣẹ iroyin BBC nibẹ ba awọn araalu kan sọrọ ti wọn si sọ pe awọn ko ti ijọba to wa lode lẹyin, amọ erongba awọn eeyan naa kii ṣe erongba gbogba araalu.

Maapu to n ṣafihan awọn eto okun to yi Iran ka

"Owo ti mo ni nipamọ le gbe mi fun oṣu meji pere, o pọ ju, ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin ti owo naa ba ti tan, ti ogun ṣi n lọ lọwọ"

Ọkunrin ẹni ogun ọdun mii ni Tehran sọ pe "mo n gbadura pe ki ogun naa ma pada bẹrẹ amọ mo gbagbọ pe yoo tun pada bẹrẹ."

O ni niṣe loun n wa iṣẹ ṣe bayii ki ori oun ma ba daru.

Ẹwẹ, obinrin kan to ti le logun ọdun ni tirẹ sọ pe oun gbagbọ pe opin yoo de ba ogun naa laipẹ.

Ọdọbinrin naa ni "Mo gbadura pe wọn maa da oju opo ayelujara pada. Mo gbadura pe ki wọn jiroro daadaa ki wọn si fẹnuko lori ohun ti wọn yoo ṣe nitori itẹsiwaju ogun yii ko daa fun awọn eeyan Iran rara."

Awọn ọmọ orilẹede Iran mii ti wọn kan si BBC lasiko ogun naa kọminu nipa oju opo ayelujara ti ko ṣiṣẹ.

Wọn ni yatọ si pe igbesẹ naa ko jẹ ki wọn ri awọn iroyin to ṣe pataki mọ, o tun ti ṣe akoba fun ọpọlọpọ ileeṣẹ atawọn oniṣowo.

Ọkunrin mii niluu Tehran ni "Ko si ẹnikẹni to n bori ogun naa ninu wọn.

Owo ti mo ni ni apamọ le gbe mi fu oṣu meji pere, o pọ ju, ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin ti owo naa ba ti tan ti ogun ṣi n lọ lọwọ."

"Ti wọn ba tilẹ fẹnuko lori adehun alaafia, pẹlu bi eto ọrọ aje wa ṣe dẹnukọlẹ yii, igbe aye wa yoo nira jọjọ"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹlomii sọ pe "Ọkan mi balẹ bayii ju igba ti Trump n ju ado oloro si wa lọ, ṣugbọn ẹru ṣi wa ninu ọkan mi.

"Ti wọn ba tilẹ fẹnuko lori adehun alaafia, pẹlu bi eto ọrọ aje wa ṣe dẹnukọlẹ yii, igbe aye wa yoo ṣoro jọjọ.

Mo n gbadura ki wọn fẹnuko fun adehun alaafia amọ inu ibẹrubojo ni mo wa."

Ọkunrin mii to ti le ni ọgbọn ọdun niluu Karaj ni oun ko gbagbọ pe Aarẹ Trump yoo yi ipinnu rẹ pada latari eto idibo abẹle to n bọ l'Amẹrika ninu oṣu Kọkanla ọdun 2026 yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ "Ninu iwoye temi, mi o ro pe Amẹrika yoo dẹyin. Ti wọn ba dẹyin, o n tumọ si pe wọn yoo lulẹ ninu eto idibo naa ni."

Ẹwẹ, loṣu Kinni ọdun yii ni ileeṣẹ ọmọ ogun Iran kọlu awọn to n ṣe iwọde lodi si ijọba ninu eyii ti wọn ti gbẹmi eeyan 6,508 ti wọn tun fi ṣikun ofin mu eeyan 53,000 mii.

Ẹwẹ, ijọba orilẹede naa ni eeyan 3,375 lo ti ba ogun Amẹrika lọ lati igba ti Amẹrika ati Israel ti bẹrẹ ogun gbigbe ti awọn.

Lọwọ yii, wọn ko tii kede igba ti ijiroro mii yoo waye laarin Amẹrika ati Iran amọ niṣe ni ọjọ iwaju Iran n mi logbologbo bayii nitori ogun ọhun.