You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Awodi: Òrìṣà òjò tí abọrẹ̀ rẹ̀ kò gbọdọ̀ ru ẹrù tàbí ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú obìnrin
Ni iluu Iwó oriṣa iṣẹmbaye kan wa nibẹ eyi ti o maa n pese ojo lasiko ti wọn ba bọọ̀; koda bi o jẹ 'ọsan ganringanrin ni wọn bọọ, ojo ni yoo pa awọn to wa si ojubọ rẹ de ile'.
Gẹ bi alaye ti awọn mọnimọni nipa aṣa oriṣa Awodi ni ilu Iwó sọ fun BBC News Yoruba pe lati ilu Ọyọ ni awọn to tẹ ilu naa do ti gbe oriṣa naa dani wa. Oloye Rẹkiatu Jimọh to jẹ olori awọn obinrin ninu ilu Iwó ṣalaye pe nibi ti oriṣ naa sọlẹ si nigba ti wọn gbe e de naa ni wọn ti n bọ ọ titi di oni yii.
Oloye Rẹkiatu Jimọh ṣalaye pe iṣẹ takuntakun ninu eyi ti abo ilu, ipese fun idagbasoke ilu wa ninu rẹ ni oriṣa Awodi yii maa n ṣe fun ilu Iwó atawọn eeyan rẹ.
'To ba ṣe aye ọjọun ni, asiko ọdun Awodi ni awọn eeyan maa n fi igbeyawo wọn si. Wọn o si wa ṣadura ni idi rẹ.'
Ki lawọn eewọ aworo oriṣa Awodi?
Nigba ti o n ba BBC News Yoruba sọrọ, Aworo Alawodi, Oloye Oduwẹmi Agbọmọla ṣalaye pe lara awọn eewọ to wa pẹlu ẹnikẹni to ba joye Aworo oriṣa naa ni pe ko gbọdọ bobinrin sun lasiko ti ọdun oriṣa naa ba ti n sunmọle, 'bi eniyan ba dan an wo ko ni de'.
Eewọ miran to rọ mọ ọ ni pe ẹnikẹni to ba kọla ko gbọdọ gbe Awodi.
Aworo Oduwẹmi ṣalaye pe: 'inu rere, inu mimọ ni wọn fi n gbe Awodi.'
"Ẹni to ba ṣagbere ko ni dele ba; ẹni tọwọ rẹ ba yi ẹjẹ to pa ọmọlọmọ ko ni dele. Bẹẹni!."
Oloye Rẹkiatu pẹlu tun sọ diẹ ninu eewọ rẹ, ninu eyi to ti ni ni kete ti eeyan ba ti di aworo Alawodi, ko gbọdọ gbe ẹru si ori rẹ mọ titi yoo fi ku.